Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 48:14-18 BIBELI MIMỌ (BM)

14. “Gbogbo yín, ẹ péjọ, kí ẹ gbọ́,èwo ninu wọn ni ó kéde nǹkan wọnyi?OLUWA fẹ́ràn rẹ̀,yóo mú ìfẹ́ inú rẹ̀ ṣẹ lórí Babiloni,yóo sì gbógun ti àwọn ará Kalidea.

15. Èmi, àní èmi pàápàá ni mo sọ̀rọ̀, tí mo pè é,èmi ni mo mú un wá,yóo sì ṣe àṣeyege ninu àdáwọ́lé rẹ̀.

16. Ẹ súnmọ́ mi, kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí,láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, n kò sọ̀rọ̀ ní àṣírí,láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣe ni mo ti wà níbẹ̀.”Nisinsinyii, OLUWA, Ọlọrun, ati Ẹ̀mí rẹ̀ ti rán mi.

17. OLUWA, Olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli, ní,“Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,tí ń kọ́ ọ ní ohun tí yóo ṣe ọ́ ní anfaani,tí ń darí rẹ, sí ọ̀nà tí ó yẹ kí o gbà.

18. “Ìbá jẹ́ pé o ti fetí sí òfin mi,alaafia rẹ ìbá máa ṣàn bí odò,òdodo rẹ ìbá lágbára bi ìgbì omi òkun.

Ka pipe ipin Aisaya 48