Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 46:4-8 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín,n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí.Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín,n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là.

5. “Ta ni ẹ óo fi mí wé?Ta ni ẹ óo fi díwọ̀n mi?Ta ni ẹ lè fi wé mi, kí á lè jọ jẹ́ bákan náà?

6. Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò,wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n.Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa.Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín.

7. Wọn á gbé e lé èjìká wọn,wọn á gbé e sípò rẹ̀, á sì dúró kabẹ̀.Kò ní le kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkankan.Bí eniyan bá ké pè é, kò lè gbọ́,kò lè yọ eniyan ninu ìṣòro rẹ̀.

8. “Ẹ ranti èyí, kí ẹ dà á rò,ẹ fi ọkàn rò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 46