Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 46:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Oriṣa Bẹli tẹríba, oriṣa Nebo doríkodò.Orí àwọn ẹran ọ̀sìn ati mààlúù ni àwọn oriṣa wọn wà.Àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rù kiri wá di ẹrù, tí àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀ ń rù.

2. Àwọn mejeeji jọ tẹríba, wọ́n jọ doríkodò,wọn ò lè gba àwọn ẹrù wọn kalẹ̀.Àwọn pàápàá yóo lọ sí ìgbèkùn.

3. “Ẹ tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu,ati gbogbo ará ilé Israẹli tí ó ṣẹ́kù;ẹ̀yin tí mo pọ̀n láti ọjọ́ tí wọ́n ti bi yín,tí mo sì gbé láti inú oyún.

4. Èmi náà ni, títí di ọjọ́ ogbó yín,n óo gbé yín títí tí ẹ óo fi hewú lórí.Èmi ni mo da yín, n óo sì máa tọ́jú yín,n óo máa gbé yín, n óo sì gbà yín là.

5. “Ta ni ẹ óo fi mí wé?Ta ni ẹ óo fi díwọ̀n mi?Ta ni ẹ lè fi wé mi, kí á lè jọ jẹ́ bákan náà?

6. Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò,wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n.Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa.Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín.

Ka pipe ipin Aisaya 46