Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 44:9-19 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Asán ni àwọn tí ń gbẹ́ ère, ohun tí inú wọn dùn sí kò lérè. Àwọn tí ń jẹ́rìí wọn kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ nǹkan, ojú ìbá le tì wọ́n.

10. Ta ló ṣe oriṣa, ta ló sì yá ère tí kò lérè?

11. Ojú yóo ti gbogbo wọn; eniyan sá ni wọ́n. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wọn pésẹ̀, kí wọ́n jáde wá. Ìpayà yóo bá wọn, ojú yóo sì ti gbogbo wọn papọ̀.

12. Alágbẹ̀dẹ a mú irin, a fi sinu iná, a máa fi ọmọ owú lù ú, a sì fi agbára rẹ̀ rọ ọ́ bí ó ti fẹ́ kí ó rí. Ebi a pa á, àárẹ̀ a sì mú un; kò ní mu omi, a sì máa rẹ̀ ẹ́.

13. Agbẹ́gilére a ta okùn sára igi, a fi ẹfun fa ìlà sí i, a fi ìwọ̀n wọ̀n ọ́n, a sì gbẹ́ ẹ bí eniyan: ẹwà rẹ̀ a dàbí ti eniyan, wọn a sì kọ́lé fún un.

14. Ó lè gé igi kedari lulẹ̀, tabi kí ó gbin igi Sipirẹsi, tabi igi Oaku, kí ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrin àwọn igi inú igbó. Ó sì lè gbin igi kedari kan, omi òjò a sì mú kí ó dàgbà.

15. Lẹ́yìn náà igi yìí di igi ìdáná: Eniyan óo gé ninu rẹ̀, yóo fi dáná yá; yóo gé ninu rẹ̀ yóo fi dáná oúnjẹ; yóo gé ninu rẹ̀, yóo fi gbẹ́ ère, yóo máa bọ ọ́. Eniyan á wá sọ igi lásán tí ó gbẹ́ di oriṣa, á sì máa foríbalẹ̀ fún un.

16. Yóo fi ìdajì rẹ̀ dáná, yóo fi se oúnjẹ, yóo fi se ẹran rẹ̀ pẹlu. Yóo jẹun, yóo jẹran, yóo yó; yóo tún yáná. Yóo ní, “Áà! Ooru mú mi nítorí mo rí iná yá.”

17. Yóo fi èyí tí ó kù gbẹ́ ère oriṣa rẹ̀, yóo máa foríbalẹ̀ fún un, yóo máa bọ ọ́, yóo máa gbadura sí i pé, “Gbà mí, nítorí ìwọ ni Ọlọrun mi.”

18. Wọn kò mọ nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Nǹkankan ti bò wọ́n lójú kí wọn má baà lè ríran; ó sì ti sé wọn lọ́kàn kí òye má baà yé wọn.

19. Kò sí ẹni tí ó ronú wò, tabi tí ó ní ìmọ̀ tabi òye, láti wí pé: “Ìdajì igi yìí ni mo fi dáná tí mo fi se oúnjẹ, tí mo sì fi se ẹran tí mo jẹ. Kí ló wá dé tí n óo ṣe fi ìyókù gbẹ́ ère kí n máa bọ ọ́? Ṣé ìtì igi lásán ló yẹ kí n máa foríbalẹ̀ fún, kí n máa bọ?”

Ka pipe ipin Aisaya 44