Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 44:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní:“Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ miẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi.

2. Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Ẹlẹ́dàá yín wí,ẹni tí ó ṣẹ̀dá yín láti inú oyún,tí yóo sì ràn yín lọ́wọ́:Ẹ má bẹ̀rù ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi,Jeṣuruni, ẹni tí mo yàn.

3. “N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹn óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ.N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín,n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín,

4. wọn óo rúwé bíi koríko inú omiàní, bíi igi wilo lẹ́bàá odò tí ń ṣàn.

5. “Ẹnìkan yóo wí pé,‘OLUWA ló ni mí.’Ẹnìkejì yóo pe ara rẹ̀ ní orúkọ Jakọbu.Ẹlòmíràn yóo kọ ‘Ti OLUWA ni’ sí apá rẹ̀yóo máa fi orúkọ Israẹli ṣe àpèjá orúkọ rẹ̀.”

6. Gbọ́ ohun tí OLUWA, ọba Israẹli ati Olùràpadà rẹ̀ wí,OLUWA àwọn ọmọ ogun, ó ní,“Èmi ni ẹni ìbẹ̀rẹ̀ ati ẹni òpin;lẹ́yìn mi, kò sí Ọlọrun mìíràn.

Ka pipe ipin Aisaya 44