Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 40:18-28 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Ta ni ẹ lè fi Ọlọrun wé,tabi kí ni ẹ lè fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19. Ṣé oriṣa ni! Tí oníṣẹ́ ọwọ́ ṣe;tí alágbẹ̀dẹ wúrà yọ́ wúrà bòtí ó sì fi fadaka ṣe ẹ̀wọ̀n fún?

20. Ẹni tí ó bá talaka, tí kò lágbára nǹkan ìrúbọ,a wá igi tí kò lè rà, tí kò sì lè ju;a wá agbẹ́gilére tí ó mọṣẹ́,láti bá a gbẹ́ ère tí kò lè paradà.

21. Ṣé ẹ kò tíì mọ̀?Ẹ kò sì tíì gbọ́?Ṣé wọn kò sọ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀,kò sì ye yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, pé:

22. Òun ni ó jókòó lókè àyíká ayé,àwọn eniyan inú rẹ̀ sì dàbí tata lójú rẹ̀.Òun ni ó ta awọsanma bí aṣọ títa,ó sì ta á bí àgọ́, ó ń gbébẹ̀.

23. Ẹni tí ó sọ àwọn ọba di ẹni ilẹ̀,ó sọ àwọn olóyè ayé di asán.

24. Wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì gbìn wọ́n,wọ́n fẹ́rẹ̀ má ì tíì ta gbòǹgbò wọlẹ̀;nígbà tí ó fẹ́ afẹ́fẹ́ lù wọ́n,tí wọ́n fi rọ bí ewéko,tí ìjì sì gbé wọn lọ bí àgékù koríko.

25. Ta ni ẹ óo wá fi mí wé,tí n óo sì dàbí rẹ̀?Èmi Ẹni Mímọ́ ni mo bèèrè bẹ́ẹ̀.

26. Ẹ gbójú sókè kí ẹ wo ojú ọ̀run,ta ni ó dá àwọn nǹkan tí ẹ rí wọnyi?Ẹni tí ó kó àwọn ìràwọ̀ sójú ọ̀run bí ọmọ ogun,tí ó ń pè wọ́n jáde lọ́kọ̀ọ̀kan,tí ó sì mọ olukuluku mọ́ orúkọ rẹ̀.Nítorí bí ipá rẹ̀ ti tó,ati bí agbára rẹ̀ ti pọ̀ tó,ẹyọ ọ̀kan ninu wọn kò di àwátì.

27. Kí ló dé, Jakọbu, tí o fi ń rojọ́?Kí ló ṣe ọ́, Israẹli, tí o fi ń sọ pé,“OLUWA kò mọ ohun tí ń ṣe mí,Ọlọrun kò sì bìkítà nípa ẹ̀tọ́ mi.”

28. Ṣé o kò tíì mọ̀,o kò sì tíì gbọ́pé Ọlọrun ayérayé ni OLUWA,Ẹlẹ́dàá gbogbo ayé.Kì í rẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a.Àwámárìídìí ni òye rẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 40