Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 39:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò náà Merodaki Baladani ọmọ Baladani, ọba Babiloni, fi ìwé ati ẹ̀bùn rán àwọn ikọ̀ kan sí Hesekaya, nítorí ó gbọ́ pé ara rẹ̀ kò ti dá tẹ́lẹ̀ ṣugbọn ara rẹ̀ ti wá le.

2. Hesekaya gbà wọ́n lálejò, ó sì fi àwọn nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n, fadaka ati wúrà, àwọn nǹkan olóòórùn dídùn ati òróró olówó iyebíye, ilé ìkó nǹkan ìjà ogun sí, ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ilé ìṣúra. Kò sí nǹkan tí ó wà ní ìpamọ́ ní ààfin Hesekaya ní ilé rẹ̀ tí kò fihàn wọ́n.

3. Lẹ́yìn náà Aisaya wolii tọ Hesekaya ọba lọ, ó bi í pé, “Kí ni àwọn ọkunrin wọnyi wí, láti ibo ni wọ́n sì ti wá sọ́dọ̀ rẹ?” Hesekaya dáhùn, ó ní, “Láti ilẹ̀ òkèèrè, ní Babiloni ni wọ́n ti wá.”

Ka pipe ipin Aisaya 39