Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 37:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Aisaya dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wí fún oluwa yín pé OLUWA ní:‘Má bẹ̀rù nítorí ọ̀rọ̀ tí o gbọ́tí iranṣẹ ọba Asiria sọ tí ó ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.

7. Ìwọ máa wò ó, n óo fi ẹ̀mí kan sí inú rẹ̀,yóo gbọ́ ìròyìn èké kan,yóo sì pada lọ sí ilẹ̀ rẹ̀.Nígbà tí ó bá dé ilén óo jẹ́ kí wọ́n fi idà pa á.’ ”

8. Rabuṣake gbọ́ pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi, nítorí náà, ó lọ bá a níbi tí ó ti ń bá àwọn ará Libina jagun.

9. Ibẹ̀ ni àwọn kan ti ròyìn fún ọba Asiria pé, Tirihaka ọba Etiopia ń bọ̀ wá gbógun tì í. Nígbà tí ó gbọ́, ó rán ikọ̀ lọ bá Hesekaya, ó ní:

10. “Ẹ sọ fún Hesekaya ọba Juda pé kí ó má jẹ́ kí Ọlọrun rẹ̀ tí ó gbójú lé ṣì í lọ́nà kí ó sọ pé ọba Asiria kò ní fi ogun kó Jerusalẹmu.

11. Ṣebí Hesekaya ti gbọ́ ohun tí àwọn ọba Asiria ṣe sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, tí wọ́n pa wọ́n run patapata. Ṣé Hesekaya rò pé a óo gba òun là ni?

12. Ṣé àwọn oriṣa orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun gbà wọ́n sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Gosani ati Harani, Resefu ati àwọn ará Edẹni tí ń gbé Telasari?

13. Ọba Hamati dà? Ọba Aripadi ńkọ́? Níbo ni ọba ìlú Sefafaimu ati ọba Hena ati ọba Ifa wà?”

14. Hesekaya gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ ọba Asiria, ó kà á. Nígbà tí ó kà á tán, ó gbéra, ó lọ sí ilé OLUWA, ó bá tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA,

15. Hesekaya bá gbadura sí OLUWA, ó ní:

Ka pipe ipin Aisaya 37