Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 37:22-32 BIBELI MIMỌ (BM)

22. ohun tí OLUWA sọ nípa rẹ̀ ni pé:“Sioni bu ẹnu àtẹ́ lù ọ́, Senakeribu,ó fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà,Jerusalẹmu ń yọ ṣùtì sí ọ.

23. Ta ni ò ń sọ̀rọ̀ aṣa sí, tí ò ń fí ń ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ò ń ṣíjú wò pẹlu ìgbéraga?Ṣé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni o ṣe irú èyí sí?

24. O rán àwọn iranṣẹ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,o ní,‘Mo ti fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi gun orí àwọn òkè gíga lọ,mo dé góńgó orí òkè Lẹbanoni.Mo ti gé àwọn igi kedari rẹ̀ tí ó ga jùlọ lulẹ̀,ati àwọn ààyò igi firi rẹ̀.Mo ti dé ibi tí ó ga jùlọ ní ilẹ̀ rẹ̀,ati igbó rẹ̀ tí ó dí jùlọ.

25. Mo gbẹ́ kànga mo sì mu omi ninu wọn.Mo ti fi ẹsẹ̀ mi tẹ gbogbo omi odò kéékèèké ilẹ̀ Ijipti ní àtẹ̀gbẹ.’

26. “Ṣé o kò tíì gbọ́ pé láti ìgbà pípẹ́,ni mo ti pinnu ohun tí mò ń mú ṣẹ nisinsinyii?Láti ayébáyé ni mo ti ṣètò rẹ̀,pé kí o wó ìlú olódi palẹ̀,kí ó di òkítì àlàpà.

27. Kí àwọn eniyan tí ń gbé inú wọnmá ní agbára mọ́,kí wọ́n wà ninu ìdààmú ati ìpayà.Kí wọ́n dàbí ewé inú okoati bíi koríko tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ hùbí koríko tí ó hù lórí òrùlé,tíí gbẹ kí ó tó dàgbà.

28. “Mo mọ ìjókòó rẹ.Mo mọ ìjáde ati ìwọlé rẹ,ati inú tí ò ń bá mi bí.

29. Nítorí pé ò ń bá mi bínú,mo sì ti gbọ́ nípa ìwà ìgbéraga rẹ,n óo sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní imú,n óo fi ìjánu bọ̀ ọ́ ni ẹnu,n óo sì dá ọ pada sí ọ̀nà tí o gbà wá.

30. “Ohun tí yóo jẹ́ àmì fún ọ nìyí Hesekaya: Ní ọdún yìí, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ. Ní ọdún tí ń bọ̀ pẹlu, ohun tí ó bá lalẹ̀ hù ni ẹ óo máa jẹ bákan náà. Ní ọdún kẹta, ẹ gbin nǹkan ọ̀gbìn, kí ẹ sì kórè rẹ̀, ẹ ṣe ọgbà àjàrà kí ẹ sì máa jẹ èso inú rẹ̀.

31. Àwọn ọmọ Juda tí ó bá ṣẹ́kù yóo fi gbòǹgbò múlẹ̀, wọn óo sì so èso.

32. Àwọn eniyan yóo ṣẹ́kù tí yóo wá láti Jerusalẹmu àwọn tí wọn yóo sá àsálà yóo wá láti orí òkè Sioni. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí.

Ka pipe ipin Aisaya 37