Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 37:12-26 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ṣé àwọn oriṣa orílẹ̀-èdè tí àwọn baba ńlá mi parun gbà wọ́n sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Gosani ati Harani, Resefu ati àwọn ará Edẹni tí ń gbé Telasari?

13. Ọba Hamati dà? Ọba Aripadi ńkọ́? Níbo ni ọba ìlú Sefafaimu ati ọba Hena ati ọba Ifa wà?”

14. Hesekaya gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ ọba Asiria, ó kà á. Nígbà tí ó kà á tán, ó gbéra, ó lọ sí ilé OLUWA, ó bá tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú OLUWA,

15. Hesekaya bá gbadura sí OLUWA, ó ní:

16. “Ìwọ OLUWA àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israẹli, ìwọ tí ìtẹ́ rẹ wà lórí àwọn Kerubu, ìwọ nìkan ni Ọlọrun gbogbo ìjọba ayé, ìwọ ni ó sì dá ọ̀run ati ayé.

17. Dẹtí sílẹ̀ OLUWA, kí o gbọ́. La ojú rẹ, OLUWA, kí o máa wo nǹkan. Gbọ́ irú iṣẹ́ tí Senakeribu rán tí ó ń fi ìwọ Ọlọrun alààyè ṣe ẹlẹ́yà.

18. Lóòótọ́ ni, OLUWA, pé àwọn ọba Asiria ti pa gbogbo orílẹ̀-èdè run tàwọn ti ilẹ̀ wọn,

19. ati pé wọ́n ju oriṣa wọn sinu iná, nítorí pé wọn kì í ṣe Ọlọrun. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n, tí wọ́n fi igi ati òkúta ṣe, nítorí náà ni wọ́n ṣe lè pa wọ́n run.

20. Nisinsinyii, OLUWA Ọlọrun wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, kí gbogbo ìjọba ayé lè mọ̀ pé ìwọ nìkan ni OLUWA.”

21. Aisaya ọmọ Amosi bá ranṣẹ sí Hesekaya, pé OLUWA, Ọlọrun Israẹli ní, nítorí pé Hesekaya ti gbadura sí òun nípa Senakeribu ọba Asiria,

22. ohun tí OLUWA sọ nípa rẹ̀ ni pé:“Sioni bu ẹnu àtẹ́ lù ọ́, Senakeribu,ó fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà,Jerusalẹmu ń yọ ṣùtì sí ọ.

23. Ta ni ò ń sọ̀rọ̀ aṣa sí, tí ò ń fí ń ṣe ẹlẹ́yà?Ta ni ò ń ṣíjú wò pẹlu ìgbéraga?Ṣé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni o ṣe irú èyí sí?

24. O rán àwọn iranṣẹ rẹ láti fi OLUWA ṣe ẹlẹ́yà,o ní,‘Mo ti fi ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun mi gun orí àwọn òkè gíga lọ,mo dé góńgó orí òkè Lẹbanoni.Mo ti gé àwọn igi kedari rẹ̀ tí ó ga jùlọ lulẹ̀,ati àwọn ààyò igi firi rẹ̀.Mo ti dé ibi tí ó ga jùlọ ní ilẹ̀ rẹ̀,ati igbó rẹ̀ tí ó dí jùlọ.

25. Mo gbẹ́ kànga mo sì mu omi ninu wọn.Mo ti fi ẹsẹ̀ mi tẹ gbogbo omi odò kéékèèké ilẹ̀ Ijipti ní àtẹ̀gbẹ.’

26. “Ṣé o kò tíì gbọ́ pé láti ìgbà pípẹ́,ni mo ti pinnu ohun tí mò ń mú ṣẹ nisinsinyii?Láti ayébáyé ni mo ti ṣètò rẹ̀,pé kí o wó ìlú olódi palẹ̀,kí ó di òkítì àlàpà.

Ka pipe ipin Aisaya 37