Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 35:7-10 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ilẹ̀ iyanrìn gbígbóná yóo di adágún omiilẹ̀ gbígbẹ yóo di orísun omi,ibi tí ọ̀fàfà fi ṣe ilé tẹ́lẹ̀ yóo di àbàtà,èèsún ati ìyè yóo máa dàgbà níbẹ̀.

8. Òpópónà kan yóo wà níbẹ̀,a óo máa pè é ní Ọ̀nà Ìwà Mímọ́;nǹkan aláìmọ́ kan kò ní gba ibẹ̀ kọjá,àwọn aláìgbọ́n kò sì ní dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀.

9. Kò ní sí kinniun níbẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ẹranko burúkú kankan kò ní gba ibẹ̀.A kò ní rí wọn níbẹ̀,àwọn tí a ti rà pada ni yóo gba ibẹ̀.

10. Àwọn tí OLUWA rà pada yóo pada,wọn óo wá sí Sioni pẹlu orin,ayọ̀ ayérayé yóo kún inú wọn.Wọn óo rí ayọ̀ ati ìdùnnú gbàìbànújẹ́ ati òṣé yóo sá kúrò níbẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 35