Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 34:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,ẹ tẹ́tí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin eniyan.Kí ilẹ̀ gbọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,kí ayé tẹ́tí sílẹ̀ pẹlu gbogbo nǹkan tí ń ti inú rẹ̀ jáde.

2. Nítorí OLUWA ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè,inú rẹ̀ sì ń ru sí àwọn eniyan ibẹ̀.Ó ti fi wọ́n sílẹ̀ fún ìparun, ó sì ti fà wọ́n kalẹ̀ fún pípa.

3. A óo wọ́ òkú wọn jùnù,òkú wọn yóo máa rùn;ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn lórí àwọn òkè.

4. Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo gbọ̀n dànùa óo ká awọsanma bí ẹni ká ìwé.Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́bí ewé tií rẹ̀ sílẹ̀ lára ìtàkùn àjàrà,àní, bí ewé tií wọ́ dànù lórí igi ọ̀pọ̀tọ́.

Ka pipe ipin Aisaya 34