Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 33:9-19 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ilẹ̀ ṣófo ó sì gbẹ,ìtìjú bá òkè Lẹbanoni,gbogbo ewéko orí rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Ṣaroni dàbí aṣálẹ̀,igi igbó Baṣani ati ti òkè Kamẹli sì wọ́wé.

10. OLUWA ní:“Ó yá tí n óo dìde,ó yá mi wàyí, n óo gbéra nílẹ̀.Àsìkò tó tí a óo gbé mi ga.

11. Èrò yín dàbí fùlùfúlù, gbogbo ìṣe yín dàbí pòpórò ọkà.Èémí mi yóo jó yín run bí iná.

12. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dàbí ìgbà tí a sun wọ́n,tí wọ́n di eérú,àní bí igi ẹ̀gún tí a gé lulẹ̀, tí a sì dáná sun.

13. Ẹ̀yin tí ẹ wà lókè réré,ẹ gbọ́ ohun tí mo ṣe;ẹ̀yin tí ẹ wà nítòsí,ẹ kíyèsí agbára mi.”

14. Ẹ̀rù ń ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà ní Sioni;ìjayà mú àwọn ẹni tí kò mọ Ọlọrun.Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná ajónirun?Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná àjóòkú?

15. Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́,ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù,tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan,tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi.

16. Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀.Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé,yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò.

17. Ojú yín yóo rí ọba ninu ọlá ńlá rẹ̀;ẹ óo fojú yín rí ilẹ̀ tí ó lọ salalu.

18. Ẹ óo máa ronú ìnira tí ẹ ti ní pé:“Níbo ni akọ̀wé wà?Níbo ni ẹni tí ń gba owó orí wà?Níbo sì ni ẹni tí ń ka ilé ìṣọ́ wà?”

19. Ẹ kò ní rí àwọn aláfojúdi náà mọ́,àwọn tí wọn ń fọ èdè tí kò ní ìtumọ̀ si yín,tí wọn ń kólòlò ní èdè tí ẹ kò gbọ́.

Ka pipe ipin Aisaya 33