Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 33:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ẹ̀rù ń ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó wà ní Sioni;ìjayà mú àwọn ẹni tí kò mọ Ọlọrun.Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná ajónirun?Ta ni ninu wa ló lè gbé inú iná àjóòkú?

15. Ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ bá tọ́, tí ó sì ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́,ẹni tí ó kórìíra èrè àjẹjù,tí ó kọ̀, tí kò gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,tí ó di etí sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ń gbèrò ati paniyan,tí ó sì di ojú rẹ̀ kí ó má baà rí nǹkan ibi.

16. Ibi ààbò ni yóo máa gbé, àpáta ńlá ni yóo jẹ́ ibi ààbò rẹ̀.Yóo máa rí oúnjẹ jẹ déédé,yóo sì máa rí omi mu lásìkò, lásìkò.

17. Ojú yín yóo rí ọba ninu ọlá ńlá rẹ̀;ẹ óo fojú yín rí ilẹ̀ tí ó lọ salalu.

18. Ẹ óo máa ronú ìnira tí ẹ ti ní pé:“Níbo ni akọ̀wé wà?Níbo ni ẹni tí ń gba owó orí wà?Níbo sì ni ẹni tí ń ka ilé ìṣọ́ wà?”

19. Ẹ kò ní rí àwọn aláfojúdi náà mọ́,àwọn tí wọn ń fọ èdè tí kò ní ìtumọ̀ si yín,tí wọn ń kólòlò ní èdè tí ẹ kò gbọ́.

20. Ẹ wo Sioni, ìlú tí a yà sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún.Ẹ óo fi ojú rí Jerusalẹmu, ibùgbé alaafia, tí àgọ́ rẹ̀ kò ní ṣídìí,tí èèkàn tí a fi kàn án mọ́lẹ̀ kò ní hú laelae,bẹ́ẹ̀ ni okùn tí a fi so ó mọ́lẹ̀ kò ní já.

21. Ṣugbọn níbẹ̀ ni OLUWA, ninu ògo rẹ̀,yóo jẹ́ odò ńlá ati odò tí ń ṣàn fún wa;níbi tí ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kò lè dé,ọkọ̀ ojú omi kò sì ní lè kọjá níbẹ̀.

22. Nítorí pé OLUWA ni onídàájọ́ wa,òun ni alákòóso wa;OLUWA ni ọba wa,òun ni yóo gbà wá là.

23. Okùn òpó-ọkọ̀ rẹ̀ ti tú,kò lè mú òpó-ọkọ̀ náà dáradára ní ipò rẹ̀ mọ́;kò sì lè gbé ìgbòkun dúró.A óo pín ọpọlọpọ ìkógun nígbà náà,kódà, àwọn arọ pàápàá yóo pín ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 33