Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 3:10-24 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Sọ fún àwọn olódodo pé yóo dára fún wọnnítorí wọn yóo jèrè iṣẹ́ wọn.

11. Ègbé ni fún àwọn eniyan burúkú,kò ní dára fún wọn.Nítorí wọn óo jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

12. Ẹ wá wo àwọn eniyan mi!Ọmọde ni àwọn olórí àwọn eniyan mi;àwọn obinrin ní ń pàṣẹ lé wọn lórí.Ẹ̀yin eniyan mi,àwọn olórí yín ń ṣì yín lọ́nà,wọ́n sì ti da ọ̀nà yín rú.

13. OLUWA ti dìde láti ro ẹjọ́ tirẹ̀;ó ti múra tán láti dá àwọn eniyan rẹ̀ lẹ́jọ́

14. OLUWA yóo pe àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí àwọn eniyan rẹ̀siwaju ìtẹ́ ìdájọ́,yóo sọ fún wọn pé;“Ẹ̀yin ni ẹ jẹ ọgbà àjàrà mi run,ohun tí ẹ jí nílé àwọn talaka ń bẹ nílé yín.

15. Kí ni ẹ rò tí ẹ fi ń tẹ àwọn eniyan mi ní àtẹ̀rẹ́,tí ẹ̀ ń fi ojú àwọn talaka gbolẹ̀?”

16. OLUWA ní,“Nítorí pé àwọn obinrin Jerusalẹmu jẹ́ onigbeeraga,bí wọn bá ń rìn, wọn á gbé ọrùn sókè gangan;wọn á máa ṣẹ́jú bí wọn tí ń yan lọ.Ṣaworo tí ó wà lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn a sì máa dúnbí wọ́n tí ń gbésẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan.

17. OLUWA yóo mú kí orí àwọn obinrin Jerusalẹmu pá;yóo ṣí aṣọ lórí wọn.”

18. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo já gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ wọn dànù; ati ṣaworo ẹsẹ̀ wọn ni, ati ẹ̀gbà orí wọn; ẹ̀gbà ọrùn wọn;

19. ati yẹtí wọn, ẹ̀gbà ọwọ́ wọn ati ìbòrí wọn.

20. Gèlè wọn ati ìlẹ̀kẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, ati ìborùn, ìgò ìpara wọn ati òògùn,

21. òrùka ọwọ́ wọn ati òrùka imú,

22. ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè ati aṣọ wọn, ati àpò

23. ati àwọn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, àwọn ìborùn olówó ńlá.

24. Òórùn burúkú yóo wà dípò òórùn dídùn ìpara,okùn yóo wà dípò ọ̀já;orí pípá yóo dípò irun tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́,aṣọ ọ̀fọ̀ yóo dípò aṣọ olówó iyebíye.Ìtìjú yóo bò yín dípò ẹwà.

Ka pipe ipin Aisaya 3