Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 3:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wò ó! OLUWA, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo múgbogbo àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé kúrò,ati àwọn nǹkan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ní Jerusalẹmu ati Juda.Yóo gba gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbójúlé,ati gbogbo omi tí wọ́n fi ẹ̀mí tẹ̀.

2. Yóo mú àwọn alágbára ati àwọn ọmọ ogun kúrò,pẹlu àwọn onídàájọ́ ati àwọn wolii,àwọn aláfọ̀ṣẹ ati àwọn àgbààgbà;

3. àwọn olórí aadọta ọmọ ogun, ati àwọn ọlọ́lá,àwọn adáhunṣe ati àwọn pidánpidán, ati àwọn olóògùn.

4. Ọdọmọkunrin ni OLUWA yóo fi jẹ olórí wọn,àwọn ọmọde ni yóo sì máa darí wọn.

5. Àwọn eniyan náà yóo máa fìyà jẹ ara wọn,olukuluku yóo máa fìyà jẹ ẹnìkejì rẹ̀,àwọn aládùúgbò yóo sì máa fìyà jẹ ara wọn.Ọmọde yóo nàró mọ́ àgbàlagbà,àwọn mẹ̀kúnnù yóo máa dìde sí àwọn ọlọ́lá.

6. Nígbà tí ẹnìkan bá dì mọ́ arakunrin rẹ̀,ninu ilẹ̀ baba rẹ̀, tí ó sọ fún un pé,“Ìwọ ní aṣọ ìlékè,nítorí náà, jẹ́ olórí fún wa;gbogbo ahoro yìí yóo sì wà lábẹ́ àkóso rẹ.”

7. Ní ọjọ́ náà, ẹni tí wọn sọ pé kí ó jẹ olórí yóo kígbe pé,“Èmi kò ní jẹ oyè alátùn-únṣe.N kò ní oúnjẹ nílébẹ́ẹ̀ ni kò sí aṣọ.Ẹ má fi mí ṣe olórí yín.”

Ka pipe ipin Aisaya 3