Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 28:23-29 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi,ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,

24. ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìnlè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró?Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà?

25. Ṣugbọn bí ó bá ti tọ́jú oko rẹ̀ tán,ṣé kò ní fọ́n èso dili ati èso Kumini sinu rẹ̀,kí ó gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ;kí ó gbin ọkà baali sí ibi tí ó yẹ,kí ó sì gbin oríṣìí ọkà mìíràn sí ààlà oko rẹ̀?

26. Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ,nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ.

27. Àgbẹ̀ kì í fi òkúta ńlá ṣẹ́ ẹ̀gúsí,bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi kùmọ̀, lu kumini.Ọ̀pá ni wọ́n fí ń lu ẹ̀gúsí;igi lásán ni wọ́n fí ń lu kumini.

28. Ǹjẹ́ eniyan a máa fi kùmọ̀ lọ ọkà alikama tí wọ́n fi ń ṣe burẹdi?Rárá, ẹnìkan kì í máa pa ọkà títí kí ó má dáwọ́ dúró.Bó ti wù kí eniyan fi ẹṣin yí ẹ̀rọ ìpakà lórí ọkà alikama tó,ẹ̀rọ ìpakà kò lè lọ ọkà kúnná.

29. Ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ìmọ̀ yìí ti ń wá pẹlu,ìmọ̀ràn rẹ̀ yani lẹ́nu;ọgbọ́n rẹ̀ ni ó sì ga jùlọ.

Ka pipe ipin Aisaya 28