Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 28:20-26 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ibùsùn kò ní na eniyan tán.Bẹ́ẹ̀ ni aṣọ ìbora kò ní fẹ̀ tó eniyan bora.

21. Nítorí pé OLUWA yóo dìdebí ó ti ṣe ní òkè Firasi,yóo bínú bí ó ti bínú ní àfonífojì Gibeoni.Yóo ṣe ohun tí ó níí ṣe,ohun tí yóo ṣe yóo jọni lójú;yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀iṣẹ́ rẹ̀ yóo ṣe àjèjì.

22. Nítorí náà ẹ má ṣe yẹ̀yẹ́,kí á má baà so ẹ̀wọ̀n yín le.Nítorí mo ti gbọ́ ìkéde ìparun,tí OLUWA àwọn ọmọ ogun pinnu láti mú wá sórí ilẹ̀ ayé.

23. Ẹ fetí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ohùn mi,ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,

24. ṣé ẹni tí ń kọ ilẹ̀ tí ó fẹ́ gbin ohun ọ̀gbìnlè máa kọ ọ́ lọ láì dáwọ́ dúró?Àbí ó lè máa kọ ebè lọ láì ní ààlà?

25. Ṣugbọn bí ó bá ti tọ́jú oko rẹ̀ tán,ṣé kò ní fọ́n èso dili ati èso Kumini sinu rẹ̀,kí ó gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ;kí ó gbin ọkà baali sí ibi tí ó yẹ,kí ó sì gbin oríṣìí ọkà mìíràn sí ààlà oko rẹ̀?

26. Yóo ṣe iṣẹ́ rẹ̀ létòlétò bí ó ti yẹ,nítorí pé Ọlọrun rẹ̀ ní ń kọ́ ọ.

Ka pipe ipin Aisaya 28