Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 25:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. ó dàbí ooru ninu aṣálẹ̀.O pa àwọn àjèjì lẹ́nu mọ́;bí òjìji ìkùukùu tií sé ooru mọ́,bẹ́ẹ̀ ni o ṣe dá orin mọ́ àwọn oníjàgídíjàgan lẹ́nu.

6. OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo fi àwọn ẹran ọlọ́ràá se àsè kan fún gbogbo orílẹ̀-èdè; yóo pa àwọn ẹran àbọ́pa, pẹlu ọtí waini, ẹran àbọ́pa tí ó sanra, tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ati ọtí waini tí ó dára.

7. Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.

8. Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

9. Wọn óo máa wí ní ọjọ́ náà pé, “Ọlọrun wa nìyí; a ti ń dúró dè é kí ó lè gbà wá, OLUWA nìyí; òun ni a ti ń dúró dè. Ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì dùn nítorí ìgbàlà rẹ̀.”

10. Nítorí OLUWA yóo na ọwọ́ ààbò rẹ̀ sórí òkè yìí. Ṣugbọn àwọn ará Moabu yóo di àtẹ̀mọ́lẹ̀ lórí ilẹ̀ wọ́n, bíi koríko tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ lórí ààtàn.

11. Wọn óo na ọwọ́ ní ààrin rẹ̀ bí ìgbà tí ẹni tí ń lúwẹ̀ẹ́ bá nawọ́ ninu omi. Ṣugbọn OLUWA yóo rẹ ìgbéraga wọn sílẹ̀, ọwọ́ wọn yóo sì rọ.

12. OLUWA yóo bi odi gíga rẹ̀ wó, yóo wó o palẹ̀, yóo sì sọ ọ́ di erùpẹ̀ ilẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 25