Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 25:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. O sọ àwọn ìlú di òkítì àlàpào sì ti pa àwọn ìlú olódi run.O wó odi gíga àwọn àjèjì, kúrò lẹ́yìn ìlú,ẹnikẹ́ni kò sì ní tún un kọ́ mọ́.

3. Nítorí náà àwọn alágbára yóo máa yìn ọ́ìlú àwọn orílẹ̀-èdè aláìláàánú yóo bẹ̀rù rẹ.

4. Nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi fún talaka,ibi ìsápamọ́sí fún aláìní lákòókò ìṣòro.Ìwọ ni ibi ààbò nígbà òjò,ati ìbòòji ninu oòrùn.Nítorí bí ìjì ti rí lára ògiribẹ́ẹ̀ ni ibinu aláìláàánú rí;

5. ó dàbí ooru ninu aṣálẹ̀.O pa àwọn àjèjì lẹ́nu mọ́;bí òjìji ìkùukùu tií sé ooru mọ́,bẹ́ẹ̀ ni o ṣe dá orin mọ́ àwọn oníjàgídíjàgan lẹ́nu.

6. OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo fi àwọn ẹran ọlọ́ràá se àsè kan fún gbogbo orílẹ̀-èdè; yóo pa àwọn ẹran àbọ́pa, pẹlu ọtí waini, ẹran àbọ́pa tí ó sanra, tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ati ọtí waini tí ó dára.

7. Lórí òkè yìí, OLUWA yóo fa aṣọ tí a ta bo àwọn eniyan lójú ya, àní aṣọ tí a dà bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.

8. Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Aisaya 25