Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 22:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa àfonífojì ìran:Kí ni gbogbo yín ń rò tí ẹ fi gun orí òrùlé lọ,

2. ẹ̀yin tí ìlú yín kún fún ariwo, tí ẹ jẹ́ kìkì ìrúkèrúdò ati àríyá?Gbogbo àwọn tí ó kú ninu yín kò kú ikú idà,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú lójú ogun.

3. Gbogbo àwọn ìjòyè ìlú yín parapọ̀ wọ́n sálọ,láì ta ọfà ni ọ̀tá mú wọn.Gbogbo àwọn tí wọn rí ni wọ́n mú,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti sá jìnnà.

4. Nítorí náà, ni mo ṣe sọ pé,“Ẹ ṣíjú kúrò lára miẹ jẹ́ kí n sọkún, kí n dami lójú pòròpòrò,ẹ má ṣòpò pé ẹ óo rẹ̀ mí lẹ́kún,nítorí ìparun àwọn ará Jerusalẹmu, àwọn eniyan mi.”

5. Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,ọjọ́ ìrúkèrúdò ati ìdágìrì ati ìdàrúdàpọ̀, ní àfonífojì ìran.Ọjọ́ wíwó odi ìlú palẹ̀ati igbe kíké láàrin àwọn òkè ńlá.

6. Àwọn ọmọ ogun Elamu gbé ọfà wọn kọ́ èjìká,pẹlu kẹ̀kẹ́-ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin,àwọn ọmọ ogun Kiri sì tọ́jú asà wọn.

7. Àwọn àfonífojì dáradára yín kún fún kẹ̀kẹ́-ogunàwọn ẹlẹ́ṣin sì dúró sí ipò wọn lẹ́nu ibodè;

8. ó ti tú aṣọ lára Juda.Ní ọjọ́ náà, ẹ gbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun ìjà tí ó wà ninu Ilé-Igbó,

9. ẹ rí i pé ibi tí ògiri ìlú Dafidi ti sán pọ̀, ẹ sì gbá omi inú adágún tí ó wà ní ìsàlẹ̀ jọ.

10. Ẹ ka iye ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu, ẹ sì wó àwọn kan palẹ̀ ninu wọn, kí ẹ lè rí òkúta tún odi ìlú ṣe.

11. Ẹ wa kòtò sí ààrin ògiri mejeeji, Kí ẹ lè rí ààyè fa omi inú odò àtijọ́ sí. Ṣugbọn ẹ kò wo ojú ẹni tí ó ṣe ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bìkítà fún ẹni tí ó ṣètò rẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ wá.

Ka pipe ipin Aisaya 22