Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 19:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ijipti nìyí:OLUWA gun ìkùukùu lẹ́ṣin, ó ń yára bọ̀ wá sí Ijipti.Àwọn oriṣa Ijipti yóo máa gbọ̀n níwájú rẹ̀,ọkàn àwọn ará Ijipti yóo sì dàrú.

2. N óo dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Ijipti,olukuluku yóo máa bá arakunrin rẹ̀ jà,àwọn aládùúgbò yóo máa bá ara wọn jà,ìlú kan yóo gbógun ti ìlú keji,ìjọba yóo máa dìde sí ara wọn.

3. Ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá àwọn ará Ijipti,n óo sọ ète wọn di òfo.Wọn yóo lọ máa wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn oriṣa ati àwọn aláfọ̀ṣẹati lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, ati àwọn oṣó.

4. Ṣugbọn n óo fi Ijipti lé aláìláàánú akóniṣiṣẹ́ kan lọ́wọ́ìkà kan ni yóo sì jọba lé wọn lórí,bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.

5. Omi odò Naili yóo gbẹ,yóo gbẹ, àgbẹkanlẹ̀.

6. Gbogbo odò wọn yóo máa rùn,gbogbo àwọn odò tí ó ṣàn wọ odò Naili ní Ijipti,ni yóo fà, tí yóo sì gbẹ:Gbogbo koríko odò yóo rà.

7. Etí odò Naili yóo di aṣálẹ̀,gbogbo ohun tí wọ́n bá gbìn sibẹ yóo gbẹ,ẹ̀fúùfù óo sì gbá wọn dànù.

8. Àwọn apẹja tí ń fi ìwọ̀ ninu odò Nailiyóo ṣọ̀fọ̀,wọn óo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn;àwọn tí ń fi àwọ̀n pẹja yóo kérora.

9. Ìdààmú yóo bá àwọn tí ó ń hun aṣọ funfun,ati àwọn ahunṣọ tí ń lo òwú funfun.

10. Àwọn eniyan pataki ilẹ̀ náà yóo di ẹni ilẹ̀,ìbànújẹ́ yóo sì bá àwọn alágbàṣe.

Ka pipe ipin Aisaya 19