Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 13:2-12 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ẹ ta àsíá ní orí òkè gíga,ẹ gbóhùn sókè sí wọn.Ẹ juwọ́, kí àwọn ológun gba ẹnu ibodè àwọn ọlọ́lá wọlé.

3. Èmi pàápàá ti pàṣẹ fún àwọn tí mo yà sọ́tọ̀,mo ti pe àwọn akọni mi, tí mo fi ń yangàn,láti fi ibinu mi hàn.

4. Gbọ́ ariwo lórí òkè, bí ohùn ọ̀pọ̀ eniyan,gbọ́ ariwo ìdàrúdàpọ̀ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń péjọ pọ̀!OLUWA àwọn ọmọ ogunní ń kó àwọn ọmọ ogun jọ fún ogun.

5. Wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè,láti ìpẹ̀kun ayé.OLUWA ń bọ̀ pẹlu àwọn ohun ìjà ibinu rẹ̀,tí yóo fi pa gbogbo ayé run.

6. Ẹ pohùnréré ẹkún,nítorí pé ọjọ́ OLUWA súnmọ́lé,yóo dé bí ìparun láti ọwọ́ Olodumare.

7. Nítorí náà ọwọ́ gbogbo eniyan yóo rọ,ọkàn gbogbo eniyan yóo rẹ̀wẹ̀sì;

8. ẹnu yóo sì yà wọ́n.Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn,wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí;wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu,ojú yóo sì tì wọ́n.

9. Wò ó! Ọjọ́ OLUWA dé tán,tìkàtìkà pẹlu ìrúnú ati ibinu gbígbóná láti sọ ayé di ahoro,ati láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.

10. Nítorí àgbájọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀runyóo kọ̀, wọn kò ní tan ìmọ́lẹ̀.Oòrùn yóo ṣókùnkùn nígbà tí ó bá yọ,òṣùpá kò sì ní tan ìmọ́lẹ̀.

11. N óo fìyà jẹ ayé nítorí iṣẹ́ ibi rẹ̀,n óo sì jẹ àwọn ìkà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.N óo fòpin sí àṣejù àwọn onigbeeraga,n óo rẹ ìgbéraga àwọn tí kò lójú àánú sílẹ̀.

12. N óo sọ eniyan di ohun tí ó ṣọ̀wọ́n ju wúrà dáradára lọ,irú eniyan yóo ṣọ̀wọ́n ju wúrà ilẹ̀ Ofiri lọ.

Ka pipe ipin Aisaya 13