Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 12:2-6 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi,n óo gbẹ́kẹ̀lé eẹ̀rù kò sì ní bà mí,nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi,òun sì ni Olùgbàlà mi.”

3. Tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa rí ìgbàlàbí ẹni pọn omi láti inú kànga.

4. Ẹ óo sọ ní ọjọ́ náà pé,“Ẹ fọpẹ́ fún OLUWA,ẹ ké pe orúkọ rẹ̀,ẹ kéde iṣẹ́ rere rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;ẹ kéde pé a gbé orúkọ rẹ̀ ga.

5. Ẹ kọ orin ìyìn sí OLUWAnítorí ó ṣe nǹkan tí ó lógo,jẹ́ kí èyí di mímọ̀ ní gbogbo ayé.

6. Ẹ̀yin tí ń gbé Sioni,ẹ hó, ẹ kọrin ayọ̀, ẹ̀yin olùgbé Sioni,nítorí Ẹni ńlá ni Ẹni Mímọ́ Israẹlití ó wà láàrin yín.”

Ka pipe ipin Aisaya 12