Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 11:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Yóo gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,yóo kó àwọn Israẹli tí a ti patì jọ.Yóo ṣa àwọn ọmọ Juda tí wọ́n fọ́nká jọ,láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé.

13. Owú jíjẹ Efuraimu yóo kúrò,a óo sì pa àwọn tí ń ni Juda lára run.Efuraimu kò gbọdọ̀ jowú Juda mọ́,bẹ́ẹ̀ ni Juda kò gbọdọ̀ ni Efuraimu lára mọ.

14. Wọn óo kọlu àwọn ará Filistini ní ìhà ìwọ̀ oòrùn,wọn yóo jọ ṣẹgun àwọn ará ìlà oòrùn.Wọn yóo sì jọ dojú ìjà kọ Edomu ati Moabu.Àwọn ará Amoni yóo gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.

15. OLUWA yóo pa Ijipti run patapata.Yóo na ọwọ́ ìjì líle sí orí odò Pirati,yóo sì pín in sí ọ̀nà meje,kí àwọn eniyan lè máa ríbi là á kọjá.

16. Ọ̀nà tí ó gbòòrò yóo wà láti Asiria, fún ìyókù àwọn eniyan rẹ̀;bí ó ti ṣe wà fún àwọn ọmọ Israẹli,nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.

Ka pipe ipin Aisaya 11