Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 10:4-21 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Kò sí ohun tí ó kù àfi kí ẹ kú lójú ogun,tabi kí ẹ ká góńgó láàrin àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò ní rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

5. Háà! Asiria!Orílẹ̀-èdè tí mò ń lò bíi kùmọ̀, ati bíi ọ̀pánígbà tí inú bá bí mi.

6. Mo rán wọn láti gbógun ti àwọn tí kò mọ Ọlọrun,ati àwọn eniyan tí wọ́n bá mú mi bínú.Pé kí wọ́n kó wọn lẹ́rù.Kí wọ́n kó wọn lẹ́rúkí wọ́n tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi ẹrọ̀fọ̀tí à ń tẹ̀ mọ́lẹ̀ níta gbangba.

7. Ṣugbọn ọba Asiria kò pa irú ète yìí,kò sì ní irú èrò yìí lọ́kàn;gbogbo èrò ọkàn rẹ̀ ni láti pa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè run

8. nítorí ó wí pé:“Ṣebí ọba ni gbogbo àwọn olórí ogun mi!

9. Ṣebí bíi Kakemiṣi ni Kalino rí,tí Hamati rí bíi Aripadi,tí Samaria kò sì yàtọ̀ sí Damasku?

10. Bí ọwọ́ mi ṣe tẹ àwọn ìlú àwọn abọ̀rìṣà,tí oriṣa wọn lágbára ju ti Jerusalẹmu ati Samaria lọ,

11. ṣé n kò ní lè ṣe sí Jerusalẹmu ati àwọn oriṣa rẹ̀bí mo ti ṣe Samaria ati àwọn oriṣa rẹ̀?”

12. Nígbà tí OLUWA bá parí bírà tí ó ń dá ní òkè Sioni ati ní Jerusalẹmu,yóo fìyà jẹ ọba Asiria fún ìwà ìgbéraga ati àṣejù rẹ̀.

13. Nítorí ó ní,“Agbára mi ni mo fi ṣe èyí,ọgbọ́n mi ni mo fi ṣe énítorí pé mo jẹ́ amòye.Mo yí ààlà àwọn orílẹ̀-èdè pada,mo kó ẹrù tí ó wà ninu ilé ìṣúra wọn.Mo ré àwọn tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ bọ́ sílẹ̀ bí alágbára ọkunrin.

14. Mo nawọ́ kó ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,bí ẹni nawọ́ kó ọmọ ẹyẹ.Mo kó gbogbo ayé,bí ẹni kó ẹyin ẹyẹ tí ó kọ ẹyin rẹ̀ sílẹ̀, tí ó fò lọ,kò sí ẹnìkan tí ó lè ṣe nǹkankan,kò sí ẹnìkan tí ó lanu sọ̀rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbin.”

15. Ǹjẹ́ fáàrí àáké lè pọ̀ ju ti ẹni tí ó ń fi gégi lọ?Tabi ayùn lè fọ́nnu sí ẹni tí ó ń fi rẹ́ igi?Ǹjẹ́ kùmọ̀ lè mú ẹni tí ó ń lò ó lọ́wọ́,tabi kí ọ̀pá mú ẹni tí ó ni í lọ́wọ́?

16. Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo rán àìsàn apanirunsí ààrin àwọn akọni ọmọ ogun rẹ̀.Dípò ohun tí wọ́n fi ń ṣe ògo,ajónirun yóo jó wọn bí ìgbà tí iná bá jóni.

17. Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóo di iná,Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóo di ahọ́n iná;yóo sì jó àwọn ẹ̀gún wẹ́wẹ́ ati ẹ̀gún ọ̀gàn rẹ̀ run ní ọjọ́ kan.

18. OLUWA yóo pa àwọn igi ńlá inú igbó rẹ̀ run,yóo pa àwọn igi eléso ilẹ̀ rẹ́ tèsotèso,bí ìgbà tí àrùn bá gbẹ eniyan.

19. Ohun tí yóo kù ninu àwọn igi igbó rẹ̀kò ní ju ohun tí ọmọde lè kà, kí ó sì kọ sílẹ̀ lọ.

20. Ní ọjọ́ náà, ìyókù Israẹli ati àwọn tí yóo yè ní agbo ilé Jakọbu, kò ní gbé ara lé ẹni tí ó ṣá wọn lọ́gbẹ́ mọ́, ṣugbọn OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli ni wọn óo fẹ̀yìn tì ní òtítọ́.

21. Àwọn yòókù yóo pada, àwọn yòókù Jakọbu yóo pada sọ́dọ̀ Ọlọrun alágbára.

Ka pipe ipin Aisaya 10