Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 10:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. wọ́n ń dínà ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní,wọn kò sì jẹ́ kí àwọn talaka ààrin àwọn eniyan mi rí ẹ̀tọ́ wọn gbà,kí wọ́n lè sọ àwọn opó di ìkógun.

3. Kí ni ẹ óo ṣe lọ́jọ́ ìjìyà yíntí ìparun bá dé láti òkèèrè?Ta ni ẹ óo sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́?Níbo ni ẹ óo kó ọrọ̀ yín sí?

4. Kò sí ohun tí ó kù àfi kí ẹ kú lójú ogun,tabi kí ẹ ká góńgó láàrin àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú.Sibẹsibẹ inú OLUWA kò ní rọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní dá ọwọ́ ìjà rẹ̀ dúró.

5. Háà! Asiria!Orílẹ̀-èdè tí mò ń lò bíi kùmọ̀, ati bíi ọ̀pánígbà tí inú bá bí mi.

6. Mo rán wọn láti gbógun ti àwọn tí kò mọ Ọlọrun,ati àwọn eniyan tí wọ́n bá mú mi bínú.Pé kí wọ́n kó wọn lẹ́rù.Kí wọ́n kó wọn lẹ́rúkí wọ́n tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi ẹrọ̀fọ̀tí à ń tẹ̀ mọ́lẹ̀ níta gbangba.

7. Ṣugbọn ọba Asiria kò pa irú ète yìí,kò sì ní irú èrò yìí lọ́kàn;gbogbo èrò ọkàn rẹ̀ ni láti pa ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè run

8. nítorí ó wí pé:“Ṣebí ọba ni gbogbo àwọn olórí ogun mi!

Ka pipe ipin Aisaya 10