Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 1:5-12 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ṣé ẹ fẹ́ kí á tún jẹ yín níyà sí i ni,àbí kí ló dé tí ẹ kò fi jáwọ́ ninu ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀ ń hù?Gbogbo orí yín jẹ́ kìkìdá egbò,gbogbo ọkàn yín sì rẹ̀wẹ̀sì.

6. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín,kò síbìkan tí ó gbádùn.Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀.Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn.

7. Orílẹ̀-èdè yín ti di ahoro,wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín.Àwọn àjèjì sì ti jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín.Ó di ahoro bí èyí tí àwọn àjèjì wó palẹ̀.

8. Ó wá ku Jerusalẹmu bí àtíbàbà ninu ọgbà àjàrà,ati bí ahéré ninu oko ẹ̀gúsí;ó wá dàbí ìlú tí ogun dótì.

9. Bí kò bá ṣe pé OLUWA àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ sí ninu wa ni,à bá rí bí i Sodomu,à bá sì dàbí Gomora.

10. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,ẹ̀yin ìjòyè Sodomu:Ẹ fetí sí ẹ̀kọ́ Ọlọrun wa,ẹ̀yin ará Gomora

11. OLUWA ní,“Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi?Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́;bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa.N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ.

12. Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi,ta ló bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi.

Ka pipe ipin Aisaya 1