Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 1:4-15 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Háà! Orílẹ̀-èdè tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀,àwọn eniyan tí ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lọ,ìran oníṣẹ́ ibi;àwọn ọmọ tí ó kún fún ìwà ìbàjẹ́!Wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀,wọn kò náání Ẹni Mímọ́ Israẹliwọ́n sì ti kẹ̀yìn sí i.

5. Ṣé ẹ fẹ́ kí á tún jẹ yín níyà sí i ni,àbí kí ló dé tí ẹ kò fi jáwọ́ ninu ìwà ọ̀tẹ̀ tí ẹ̀ ń hù?Gbogbo orí yín jẹ́ kìkìdá egbò,gbogbo ọkàn yín sì rẹ̀wẹ̀sì.

6. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ dé orí yín,kò síbìkan tí ó gbádùn.Gbogbo ara yín kún fún ọgbẹ́ ati egbò tí ń ṣẹ̀jẹ̀.Ẹnikẹ́ni kò wẹ egbò yín, wọn kò dì wọ́n,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi òògùn sí wọn.

7. Orílẹ̀-èdè yín ti di ahoro,wọ́n ti dáná sun àwọn ìlú yín.Àwọn àjèjì sì ti jẹ ilẹ̀ yín run níṣojú yín.Ó di ahoro bí èyí tí àwọn àjèjì wó palẹ̀.

8. Ó wá ku Jerusalẹmu bí àtíbàbà ninu ọgbà àjàrà,ati bí ahéré ninu oko ẹ̀gúsí;ó wá dàbí ìlú tí ogun dótì.

9. Bí kò bá ṣe pé OLUWA àwọn ọmọ ogun dá díẹ̀ sí ninu wa ni,à bá rí bí i Sodomu,à bá sì dàbí Gomora.

10. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA,ẹ̀yin ìjòyè Sodomu:Ẹ fetí sí ẹ̀kọ́ Ọlọrun wa,ẹ̀yin ará Gomora

11. OLUWA ní,“Kí ni gbogbo ẹbọ yín jámọ́ fún mi?Àgbò tí ẹ fi ń rú ẹbọ sísun sí mi ti tó gẹ́ẹ́;bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọ̀rá ẹran àbọ́pa.N kò ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ mààlúù tabi ti ọ̀dọ́ aguntan tabi ti òbúkọ.

12. Nígbà tí ẹ bá wá jọ́sìn níwájú mi,ta ló bẹ̀ yín ní gbogbo gìrìgìrì lásán, tí ẹ̀ ń dà ninu àgbàlá mi.

13. Ẹ má mú ẹbọ asán wá fún mi mọ́;ohun ìríra ni turari jẹ́ fún mi.Àjọ̀dún ìbẹ̀rẹ̀ oṣù titun, ọjọ́ ìsinmi, ati pípe àpéjọ.Ara mi kò gba ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ ẹ̀sìn mọ́.

14. Ninu ọkàn mi, mo kórìíra àwọn àjọ̀dún oṣù tuntun yín, ati àwọn àjọ̀dún pataki yín.Wọ́n ti di ẹrù wúwo fún mi,n kò lè gbé e mọ́, ó sú mi.

15. “Bí ẹ bá tẹ́wọ́ adura,n óo gbé ojú mi kúrò lọ́dọ̀ yín.Ẹ̀ báà tilẹ̀ gbadura, gbaduran kò ní gbọ́;nítorí ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀,

Ka pipe ipin Aisaya 1