Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Títù 3:3-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà kan rí, àwa pàápàá jẹ́ opè àti aláìgbọ́ràn, àti tàn wá jẹ, a sè ti sọ wá di ẹrú fún onírúurú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ àti adùn ayé. À ń gbé ìgbé-ayé àrankan àti owú kíkorò, a jẹ́ ẹni ìríra, a sì ń kórira ọmọ ẹnìkejì wa pẹ̀lú.

4. Ṣùgbọ́n nígbà tí inú rere àti ìfẹ́ Ọlọ́run Olùgbàlà wa farahàn,

5. Ó gbà wá là. Kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí àwa ṣe nínú òdodo bí kò ṣe nítorí àánú rẹ̀. Ó gbà wá là, nípaṣẹ̀ ìwẹ̀nù àtúnbí àti ìsọdọ̀tun ti Ẹ̀mí Mímọ́,

6. èyí tí tú lé wa lórí ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́ nípaṣẹ̀ Jésù Kírísítì Olùgbàlà wá.

7. Tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó jẹ́ wí pé lẹ́hìn tí a tí dáwa láre nípaṣẹ̀ oore-ọ̀fẹ́, kí a lè jẹ́ ajùmọ̀jogún ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.

8. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí. Mo sì fẹ́ kí ó ṣe ìtẹnumọ́ rẹ̀, kí àwọn tí wọ́n ti gbàgbọ́ nínú Olúwa le kíyèsí láti máa fi ara wọn jìn fún iṣẹ́ rere. Nǹkan wọ̀nyìí dára, wọ́n sì jẹ èrè fún gbogbo ènìyàn.

9. Ṣùgbọ́n yẹra kúrò nínú àwọn ìbéèrè òmùgọ̀, àti ìtàn ìran, àti àríyànjiyàn àti ìjà nípa ti òfin, nítorí pé àwọn nǹkan báyìí jẹ́ aláìlérè àti asán.

10. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin yín, ẹ bá a wí lẹ́ẹ̀kínní àti lẹ́ẹ̀kejì. Lẹ́yìn náà, ẹ má ṣe ní ohunkóhun íṣe pẹ̀lú rẹ̀.

Ka pipe ipin Títù 3