Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Títù 1:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, afínnú àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrin àwọn onílà.

11. Ó gbọdọ̀ pawọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí wí pé wọ́n ń pa agbo Ọlọ́run run, nípaṣẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ èyí tí wón ń kọ́ni. Èyí ni wọ́n ń ṣe fún ere àìsòdodo.

12. Ọ̀kan nínú àwọn wòlíì wọn pàápàá sọ wí pé, “òpùrọ́ ní àwọn ará Kírétè, wọ́n jẹ́ ẹranko búburú tí kò sé tù lójú, ọ̀lẹ, oníwọ̀ra”.

13. Òtítọ́ ni ẹ̀rí yìí. Nítorí náà, bá wọn wí gidigidi, kí wọn baà lè yè koro nínú ìgbàgbọ́

Ka pipe ipin Títù 1