Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 6:14-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́.

15. Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé, nísinsinyìí, a lè tẹ̀ṣíwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ láì bìkítà? (Nítorí ìgbàlà wa kò dúró nípa òfin mọ́, bí kò ṣe nípa gbígba oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run)

16. Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ (pẹ̀lú ikú) tàbí ìgbọ́ràn (pẹ̀lú ìdáláre). Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá yọ̀ǹda ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀.

17. Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti se ìgbọ́ràn, pẹ̀lú ọkàn yín, sí ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́.

18. Nísinsìnyìí, ẹ ti dòminira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tíí ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.

19. Èmi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà báyìí, ní lílo àpèjúwe àwọn ẹrú àti àwọn ọ̀gá nítorí kí ó ba le yé yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ìgbà kan jẹ́ ẹrú sí oríṣiríṣi ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ ní láti di ẹrú gbogbo èyí tíi ṣe rere tí ó sì jẹ́ Mímọ́.

20. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin kò ṣe wàhálà púpọ̀ pẹ̀lú òdodo.

21. Àti pé, kí ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ̀n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsìnyìí láti ronu nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń sọ nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé.

22. Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ìránṣẹ́ Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun.

23. Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nípaṣẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa.

Ka pipe ipin Róòmù 6