Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 5:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ṣùgbọ́n ikú jọba láti ìgbà Ádámù wá títí fi di ìgbà ti Mósè, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Ádámù, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀.

15. Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jésù Kírísítì, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀.

16. Kì í ṣe bí nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà: Nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre,

17. Ǹjẹ́ bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà; mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jésù Kírísítì.

18. Ǹjẹ́ bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè.

19. Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́sẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.

20. Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá.

21. Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jésù Kírísítì Olúwa wa.

Ka pipe ipin Róòmù 5