Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 2:26-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí akọ nílà bí?

27. Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà

28. Kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní òde ni Júù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní ara ni ìkọlà:

29. Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Ka pipe ipin Róòmù 2