Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 2:18-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dárajù lọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin;

19. Tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn,

20. Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́,

21. Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí?

22. Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kóríra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹ́ḿpìlì ní olè bí?

23. Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin?

24. Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ, “Orúkọ Ọlọ́run sáà di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrin àwọn aláìkọlà nítorí yín,”

25. Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà.

26. Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí akọ nílà bí?

27. Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà

Ka pipe ipin Róòmù 2