Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 2:13-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni aláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dáláre.

14. Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà àdánidá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin.

15. Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsìnyí.

16. Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jésù Kírísítì ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere mi.

17. Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálò rẹ̀ sí Ọlọ́run,

18. Tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dárajù lọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin;

19. Tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn,

20. Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́,

21. Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí?

22. Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kóríra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹ́ḿpìlì ní olè bí?

23. Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin?

24. Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ, “Orúkọ Ọlọ́run sáà di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrin àwọn aláìkọlà nítorí yín,”

25. Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà.

26. Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí akọ nílà bí?

Ka pipe ipin Róòmù 2