Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 14:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí ìdí èyí náà ni Kírísítì fi kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààye.

10. Èése nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arakùnrin rẹ lẹ́jọ́? tàbì èése tí ìwọ sì ń fi ojú ẹ̀gàn wo arakùnrin rẹ? Nítorí olúkúlùkù wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.

11. A ti kọ ìwé rẹ̀ pé:“ ‘Níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè,’ ni Olúwa wí‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi;gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”

12. Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.

13. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yé dá ara wa lẹ́jọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má se fi òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arakùnrin yín.

14. Bí ẹni tí ó wà nínú Jésù Olúwa, mo mọ̀ dájú gbangba pé kò sí oùnjẹ tó jẹ́ àìmọ́ nínú ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnìkẹ́ni ba kà á sí àìmọ́, òun ni ó se àìmọ́ fún.

15. Bí inú arakùnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí ohun tí ìwọ́ jẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má se fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kírísítì kú fún di ẹni ègbé.

Ka pipe ipin Róòmù 14