Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 14:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí ìjọba ọ̀run kì í se jíjẹ àti mímu, bí kò se nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Èmí Mímọ́,

18. nítorí ẹni tí ó bá sin Kírísítì nínú nǹkan wọ̀nyí ni ó se ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ní ìyìn lọ́dọ̀ ènìyàn.

19. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró.

20. Má se dí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ nítorí oúnjẹ. Gbogbo oúnjẹ ni ó mọ́, sùgbọ́n ohun búburú ni fún ẹni náà tí ó jẹ ohunkóhun tí ó le mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀.

21. Ó sàn kí a má jẹ ẹran tàbí mu wáìnì tàbí se ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ subú.

22. Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nípa ohun tí ohun gbà.

23. Ṣùgbọ́n ẹni náà tí ó se iyèméjì ni a ti dá lẹ́bi tí ó ba jẹ ẹ́, nítorí kò wá nípa ìgbàgbọ́; bẹ́ẹ̀ sì ni, ohun gbogbo tí kò bá ti ipa ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀sẹ̀ ni.

Ka pipe ipin Róòmù 14