Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 11:33-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!Àwámáridí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!

34. “Nítorí tali ó mọ inú Olúwa?Tàbí tani íṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”

35. “Tàbí tani ó kọ́ fifún un,tí a kò sì san padà fún u?”

36. Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.

Ka pipe ipin Róòmù 11