Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 11:17-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ṣùgbọ́n a ti ké díẹ̀ nínú ẹ̀ka Ábúráhámù, tí í ṣe àwọn Júù kúrò. Ẹ̀yin aláìkọlà, tí a lè wí pé ó jẹ́ ẹ̀ka igi búburú ni a fi sí ipò àwọn Júù. Nítorí náà, nísinsinyí, í se é ṣe fún yín láti gba ìbùkún tí Ọlọ́run ṣe ìpinnu fún Ábúráhámù àti àwọn ọmọ rẹ̀, èyí ni pé, ẹ ń pín nínú oúnjẹ ọlọ́ràá tí ó jẹ́ ti igi àrà ọ̀tọ̀ fún Ọlọ́run.

18. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe gbéraga nítorí pé a fi yín sí ipò àwọn ẹ̀ka tí a ké kúrò. Nǹkan tí ó mú kí ẹ ṣe pàtàkì ni pé, ẹ jẹ́ ẹ̀ka igi Ọlọ́run yìí. Ẹ rántí pé, ẹ̀ka igi lásán ni yín, ẹ kì í ṣe gbòngbò.

19. Ó ṣe é ṣe fún un yín kí ẹ wí pé, “Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti ké ẹ̀ka igi wọ̀nyí kúrò, tí ó sì fi wá sí ipò wọn, a sàn jù wọ́n lọ”

20. Ẹ kíyèsára! Ẹ sì rántí pé, a ké àwọn ẹ̀ka wọ̀n ọn nì tí í ṣe Júù kúrò nítorí pé wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́. Àti pé, ẹ̀yin sì wà níbẹ̀ nítorí pé ẹ̀yin gbàgbọ́. Ẹ má ṣe gbéraga, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀, kí ẹ sì dúpẹ́, kí ẹ sì, máa sọ́ra gidigidi.

21. Nítorí pé bí Ọlọ́run kò bá dá àwọn ẹ̀ka igi tí ó fi síbẹ̀ lákọ́kọ́ sí, ó dájú wí pé, kò ní dá ẹ̀yin náà sí.

22. Nítorí náà wo ore àti ìkáànú Ọlọ́run lórí àwọn tí ó subú, ìkàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, ọrẹ, bi ìwọ bá dúró nínú ọrẹ rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò.

23. Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀.

24. Nítorí bí a bá ti ke ìwọ kúrò lára igi ólífì ìgbẹ́ nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì gbé ìwọ lé orí igi ólífì rere lòdì sí ti ẹ̀dá; mélòómélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi ólífì wọn?

25. Ará, èmi kò sá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má baá ṣe ọlọgbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Ísírẹ̀lì ní apákan, títí kíkún àwọn aláìkọlà yóò fi dé.

26. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gba gbogbo Ísírẹ́lì là, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Ní Síónì ni Olúgbàlà yóò ti jáde wá,yóò sì yìí àìwà-bí-Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ Jákọ́bù.

27. Èyí sì ni májẹ̀mú mi fún wọn.Nígbà tí èmi yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.”

28. Nípa ti ìyìn rere, ọ̀ta ni wọ́n nítorí yín; bí ó sì ṣe ti ìyànfẹ́ ni, olùfẹ́ ni wọ́n nítorí ti àwọn baba.

Ka pipe ipin Róòmù 11