Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 10:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀yin ará, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi ni pé, kí àwọn Júù rí ìgbàlà.

2. Mo mọ irú ìfẹ́ àti ìtara tí wọ́n ní sí ọlá àti ògo Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ọ̀nà ìsìnà ni wọn ń gbà wá Ọlọ́run;

3. Ìdí ni pé, wọ́n ń gbìyànjú láti hu ìwà rere nípa pípa òfin àti àṣà ìbílẹ̀ àwọn Júù mọ́, kí wọn báà lè rí ojú rere Ọlọ́run. Kò yé wọn pé, Kírísítì ti kú láti mú wọn dọ́gba pẹ̀lú Ọlọ́run. Òfin àwọn Júù àti àṣà ìbílẹ̀ wọn kì í ṣe ọ̀nà tí Ọlọ́run lè fi gba ènìyàn là.

4. Títí ìsinsin yìí, wọn kò ì tíì mọ̀ pé, Kírísítì kú láti pèsè ohun gbogbo tí wọ́n ń fi àníyàn wá kiri nípa òfin fún àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, ó ti fi òpin sí gbogbo rẹ̀.

Ka pipe ipin Róòmù 10