Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 9:36-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

36. Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.

37. Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan

38. Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

Ka pipe ipin Mátíù 9