Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 9:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsí i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsìn yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.”

19. Jésù dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

20. Ṣì kíyèsí i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀.

21. Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sáà le fi ọwọ́ kan ìsẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”

22. Nígbà tí Jésù sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dà.” A sì mú obìnrin náà lára dà ni wákàtí kan náà.

23. Nígbà tí Jésù sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afọnfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń paríwó.

24. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà.

25. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde.

26. Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.

27. Nígbà tí Jésù sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dáfídì.”

28. Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jésù bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?”Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.”

29. Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.”

Ka pipe ipin Mátíù 9