Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 8:32-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ!” Nígbà tí wọn sì jáde, wọn lọ sínú agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó, gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà sì rọ́ gììrì sọ̀ kalẹ̀ bèbè-odò bọ́ sínú òkun, wọ́n sì ṣègbé nínú omi.

33. Àwọn ẹni tí ń ṣọ wọn sì sá, wọ́n sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìlú, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, àti ohun tí a ṣe fún àwọn ẹlẹ́mìí-èṣù.

34. Nígbà náà ni gbogbo ará ìlú náà sì jáde wá í pàdé Jésù. Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́, kí ó lọ kúrò ní agbégbé wọn.

Ka pipe ipin Mátíù 8