Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 8:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ó ti orí òkè sọ̀ kalẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

2. Sì wò ó, adẹ́tẹ̀ kan wà, ó wá ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mi di mímọ́.”

3. Jésù si nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́”. Lójú kan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́!

4. Jésù sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnì kan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlúfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mósè pa laṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.”

5. Nígbà tí Jésù sì wọ̀ Kápánámù, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.

6. O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ-ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ àrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”

7. Jésù sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.”

8. Balógun ọ̀rún náà dahùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ-ọ̀dọ̀ mi láradá.

9. Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹnì kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”

Ka pipe ipin Mátíù 8