Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 6:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ẹ fún wa ní oúnjẹ oòjọ́ wa lónìí

12. Ẹ dárí gbèsè wa jì wá,Bí àwa ti ń dárí ji àwọn ajigbésè wa,

13. Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdẹwò,Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’

14. Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dárí jì yín.

15. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò níí dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.

Ka pipe ipin Mátíù 6