Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 5:7-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Alábùkún-fún ni àwọn aláàánú,nítorí wọn yóò rí àánú gbà.

8. Alábùkún-fún ni àwọn ọlọ́kàn mímọ́,nítorí wọn yóò rí Ọlọ́run.

9. Alábùkún-fún ni àwọn tonílàjà,nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.

10. Alábùkún-fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí,nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodonítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.

11. “Alábùkún-fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, ti wọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi.

12. Ẹ yọ̀, kí ẹ̀yin sì fò fún ayọ, nítorí ńlá ni èrè yín ní ọ̀run, nítorí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ń bẹ ṣáájú yín.

13. “Ẹ̀yin ni iyọ̀ ayé. Ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu kí ni a ó fi mú un dùn? Kò tún wúlò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe pé kí a dà á nù, kí ó sì di ohun tí ènìyàn ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14. “Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fara sin.

15. Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òṣùnwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé.

16. Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.

17. “Ẹ má se rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ.

18. Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, àmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé ofin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ.

19. Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jù lọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jù lọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń sewọn, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run.

20. Nítorì náà ni mọ ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisí àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.

21. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’

Ka pipe ipin Mátíù 5