Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 5:40-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Bí ẹnì kan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú.

41. Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì.

42. Fi fún àwọn tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, má ṣe kọ̀ fún ẹni tí ó fẹ́ ya láti lọ́wọ́ rẹ.

43. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Fẹ́ràn aládúgbo rẹ, kí ìwọ sì kórírà ọ̀ta rẹ̀.’

44. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀ta yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín,

45. Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín bi ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo.

46. Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó-òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́?

47. Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn? Àwọn abọ̀rìṣà kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí?

48. Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.

Ka pipe ipin Mátíù 5