Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 4:2-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á.

3. Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí àwọn òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”

4. Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn pé, “A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa àkàrà nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ ti ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wá.’ ”

5. Lẹ́yìn èyí ni èṣù gbé e lọ sí ìlú mímọ́ náà; ó gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹ̀ḿpìlì.

6. Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, Bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sa ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí tìrẹwọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọnkí ìwọ kí ó má baà fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

7. Jésù sì da lóhùn, “A sìáà ti kọ ọ́ pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

8. Lẹ́ẹ̀kan sí i, èṣù gbé e lọ sórí òkè gíga, ó sì fi gbogbo orílẹ̀-èdè ayé àti gbogbo ẹwà wọn hàn án.

9. Ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ, bí ìwọ bá foríbalẹ̀ tí o sì sìn mi.”

10. Jésù wí fún un pé, “Kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, ìwọ Sàtánì! Nítorí a ti kọ ọ́ pé: ‘Olúwa Ọlọ́run rẹ ni kí ìwọ kí ó fi orí balẹ̀ fún, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ ó sìn.’ ”

Ka pipe ipin Mátíù 4