Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 4:13-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ó kúrò ní Násárẹ́tì, ó sì lọ ígbé Kápánámù, èyí tí ó wà létí òkun Sébúlónì àti Náfítálì.

14. Kí èyí tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Àìsáyà lè ṣẹ pé:

15. “Iwọ Sébúlónì àti ilẹ̀ Náfítalìọ̀nà tó lọ sí òkun, ní ọ̀nà Jọ́dánì,Gálílì ti àwọn aláìkọlà,

16. Àwọn ènìyàn tí ń gbé ni òkùnkùntí ri ìmọ́lẹ̀ ńlá,àwọn tó ń gbé nínú ilẹ̀ òjijì ikuni ìmọ́lẹ̀ tan fún.”

17. Láti ìgbà náà lọ ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronú pìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”

18. Bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Símónì, ti à ń pè ní Pétérù, àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń ju sọ àwọn wọn sínú òkun nítorí apẹja ni wọ́n.

19. Jésù wi fun wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”

20. Lójú kan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀lé e.

21. Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú Sébédè baba wọn, wọ́n ń dẹ àwọ̀n wọn, Jésù sì pè wọn náà pẹ̀lú.

22. Lójú kan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú-omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

23. Jésù sì rin káàkiri gbogbo Gálílì, ó ń kọ́ni ní sínágọ́gù, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba ọ̀run. ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn gbogbo àti àìsàn láàrin gbogbo ènìyàn.

24. Òkìkí rẹ̀ sì kàn yí gbogbo Síríà ká; wọ́n sì gbé àwọn aláìsàn tí ó ní onírúurú àrùn, àwọn tí ó ní ìnira ẹ̀mí èṣù, àti àwọn ti o ní wárápá àti àwọn tí ó ní ẹ̀gbà; ó sì wò wọ́n sàn.

Ka pipe ipin Mátíù 4